Itan so wipe isele yii wa’ye ni agbegbe Damascusi. Onisowo kan ran omo odo re lo si oja. Nigbati iranse naa pada de, nse ni o n gbon jinini ti eru si n ba; o wipe, “Nigbati mo wa ni oja, eniyan kan ti mi lojji laarin ero. Mo boju wehin, mo si ri wipe Iku ni oti mi lojiji.
O wo mi, o si deru ba mi. Oga mi, ejowo e ya mi ni esin ki nle sa lo fun Iku. Emi yio gun esin lo si ilu Samarra. Nibe ni ngo sa pamo si ti Iku ki yio fi se awari mi.”
Ni ojo yii kan naa, nigbati o se die, onisowo yii funra re lo si oja, o si ri Iku laarin eero. O wi fun pe, “Kini ode ti o fi deruba iranse mii ni owuro eni?”
Iku fesi wipe, “Emi ko deruba o, kayefi kan se mi ni o. iyalenu ni oje funmi lati ri iranse re ni Damascusi, nitori wipe, adehun wa wa ni ilu Samarra ni asele oni yii!!!”
N’ibo ni iwo yio sa ere de? Apa ibo ni iwo yio saare sii?
A ti gbo nipa opolopo eniyan ti won baa n saa fun ibi kan, tabi omiran, ni o je wipe inu ibi ti won sa fun yii ni won maa n kosi.
Itan kan wa ti arabinrin kan to fe se idaabobo awon omo re nitori iku ojiji. O te siwaju lati darapo mo egbe ti won se ileri aabo ati ipamo fun. Leyin ti o darapo mo won, “idiyele omo egbe” gbo do di sisan. Nitori idi eyi, o fi ikan ninu awon omo re rubo. Nigbati iye re yio soji, meta ninu awon re merin ti se alabapade iku ti ko se se alaaye. Igba naa ni obinrin yii sa to Jesu Kristi lo fun aabo.
“Oruko Oluwa ile iso agbara ni: olododo sa wo inu Re, o si ye.” Iwe Owe 18:10
Mase duro de ewu ki o kan lekun re ki o to maa saare kijo kijo. Sa to Jesu Kristi ki o le so wipe, “Eniti o n gbe ninu mi, ju eniti o n gbe ninu aye lo.” Johannu Kini 4:4.
E wo ni o wu o, lati sato Jesu Kristi fun aabo ati ipamo, tabi o wu o ki o sa lo si Samarra?
A fe gba o ni iyanju lati gbadura yii lesekese:
“Olorun Alagbara, Iwo ni o se eda orun ati aye. Iwo ni Eleda mi. Mo wa si odo Re nisisinyi, mo si toro idariji fun gbogbo ese mi, gba okan mi la nipase Jesu Kristi. Mo jewo pelu enu mi wipe Jesu Kristi ni Oluwa. Mo gbagbo wipe Olorun Baba ji Jesu dide kuro ninu oku, O si wa laaye titi lai. Mo gba Jesu Kristi gegebi Oluwa ati Olugbala mi. Oluwa Jesu, wa sinu aye mi, fi Emi Re sinu mi ki o si fun mi ni agbara lati gbe igbe aye mi ni liana ofin Olorun. Amin.”
Tio ba gbadura yii, a gbadura wipe Emi Mimo yio toka re si ile ijosin Kristieni tooto kio le ni imo si nipa Olorun.