Mohammodu dagba laarin eya Fulani, osi bere si ni da maalu ni igbati o pe omo odun mefa. O se eleyi fun bii odun mewa ki o to lo si ile iwe Keu. Leyin opolopo odun ni ile-iweKeu. Leyin opolopo odun ni ile-iwe Keu, o pada sile. NI ale ojo kan, o la ala kan tio deruba gidigidi.
O ri awon eniyan ni eba ona ti won j’erora. O gba enu aganrandi wole awon eniyan si mu, won si bere sii naa. Leyin eyi won tun mu wo yara kan tio gbona gaan. O gbona de ibi wipe eran ara re bere sii si kuro lara re. Bi oti bere sii kigbe rara, ti o tun gbiyanju lati fie se si ilekun ni o ba taji loju orun. Ko ri orun sun mo titi ile ojo keji fii mo. Ni ale ojo keji, o la ala miran. Ni ote yii, won mu gba ona miran, osi ri awon oku ti won ti n raa. O tun de enu aganrandi yii kan naa, won naa, won tun mu lo yara kan naa ti o ti wa tele. Eran ara re bere si yoo (bii ori ti oorun ti pa) kuro lara re nigbati okunrin kan ti o wo aso funfun yo si.
Lojiji, yara naa mu otutu, awon eniyan ti won da seria fun un poora. Okunrin naa naa owo re si osi di owo Mohammodu mu, ti o si n wipe “Omo mi, ewo ni iwo nse nihin? Se iwo fe kin mu o lo ile?” Mohammodu wipe, “Ni iseju aya kan mo ti pada de ile, okunrin naa si wi fun mi pe, “Mo ni ife re, omo mi.”
Leyin ose meji, Mohammodu la ala keta. O wa ninu igbo koto giriwo kan si wa niwaju re, kosi mo bi yio se dakoja. Nigbati o wo inu koto naa, eru baa gidigidi o sir o wipe o sese ki ohun subu sinu re ki ohun si ku. Ori okunrin kan ti o wo aso dudu ti o si nrin kanmokanmo. Okunrin yii so fun wipe kiniun kan mbo leyin Mohammodu, ki o fo koto naa koja ki kiniun naa to de baa.Mohammodu gbo bi kiniun naa ti se n buu ramu ramu. Bi o se fe fo, okunrin ti o wa ninu aso funfun lati inu ara re ti tele yosiwaju re, osi beere lowo re, “Omo mi, ibo ni iwo nlo?” Okunrin alaso dudu poora ati bibuu kiniun naa si dawo duro. Mohammodu so fun okunrin ti o wo aso funfun pe ile ni ohun lo. O beere lowo Mohammodu ti o ba fe iranlowo. Okunrin alaso funfun yii naa ese koja koto yii. Bi oti se eleyi, koto naa dii patapata osi wi fun Mohammodu pe ki o koja ki o si maa lo ile. Nigbati won ti sun mo ile Mohammodu, okunrin yii wi fun pe, “Mo nife re, omoo mi.”
Fun ale ojo mefa, Mohammodu la iru awon ala wonyi.ni igba gbogbo, o maa n ri ara re ni orisirisi ibi, ikikibi ti iba wa, okunrin alaso funfun yii kan naa ma n ranlowo. Ninu ala ti o gbeyin (eyi ti se ala kesan), Mohammodu joko si abe igi kan ti o si nka awon iwe ti ko ni oye re. okunrin ti o wa ninu ala funfun yii (Jesu) joko si egbe re. o beere lowo Mohammodu kini nkan ti o n ka, Mohammodu si dahun wipe ohun gbiyanju lati fi imo kunmo ni. Jesu beere lowo re bi o ba fe iranlowo pe ohun le toka awon nkan pato ti yio ka. Jesu mu iwe kan o si wipe, “Iwe yii wa lati odo Oluwa, osi ni ise lati odo Olorun ninu re. Ninu iwe yii, Emi yio fi han o awon ese ti yio ran o lowo.” Jesu ka oro Olorun si Mohammodu ati lati inu iwe Johannu 14:6 ti o wipe, “Emi ona, otito ati iye. Kosi eniti o le wa si odo Baba lai se nipase mi.”
O se alaye eleyi fun Mohammodu osi wi fun pe Ohun ni ona ati Olugbala gbogbo aye. Jesu tun so fun wipe yio koju iponju leyin ti o ba di omo leyin Kristi. O wi fun Mohammodu pe ohun fe je Olugbala re ati wipe ohun ni okunrin ti Mohammodu ti maa n ri loju ala re, eniti o ko yo. Nigbati Jesu so fun Mohammodu pe ohun fe fun ni igbala, osi beere, “Nje iwo yio gba bii?” Mohammodu si dahun wipe beeni, Jesu si poora.
Ni ojo keji MOhammodu lo ba enikan ti o je ore re ti n se Kristieni lati so fun ala re, Ore re yii mu lo baa won odo kunrin lati ile ijoosin miran, won si mu Mohammodu to Kristi. O so fun awon obi re pe ohun ti di Kristeni bayi. Leyin osu pupo, Baba Mohammodu fipa mu lati mu majele. O pase fun awon okunrin ni abule lati yiipo Mohammudu ki o maa le sako. Bee, ni ojo meji saaju asiko yii Jesu farahan Mohammodu o si wi fun pe isoro kiosro ti koba dojuko, Ohun yio la ona fun. Mohammodu beere lowo baba re bi ohun bale gbadaura ki ohun to gbe majele naa mi. o gbadura osi gbe naa mi, o si lo sun. ni owuro ojo keji si iyalaenu baba re, MOhammodu si wa laaye. Leyin eyi, awon ebi re gbiyanju lati pa a, won ta ni ofo ti oro wa laara re. osu kan gbako ni o lo nil eiwosan, sugbon o boti isele yii bakan naa.
Leyin gbogbo ilepa lati da emi re legbodo, ebi re gbiyanju awon ona miran lati parowa si lati fie sin Kristieni sile. Baba re fun ni oogorun maalu, osi so fun pe, o le fe iyawo meta ti o ba gba lati esin Kristieni ti.Leyin oreyin, Mohammodu se ipinu- sugbon lati fi ile baba re sile ni. O dupe lowo baba re fun malu ati ebun iyawo meta, o wa so wipe “E o ti baa won ini ti Jesu se ileri lati bapade. Ti e ba se ileri ti e ba si fara mo latii baa won ini wonyi pade, o dabe. Nje eyin mo ona lati fun mi ni iye tiit lai?” baba re dahun wipe rara. Mohammodu so fun baba re pe niwon igba ti ko ti le fun ohun ni iye ayeraye, ko si bi ohun se le fi Jesu Kristi sile.
Leyin odun die, nigbati o wa lori akete iku re, baba Mohammodu beere fun idariji lati owo Mohammodu, osi ni ohun ti se tan lati gba Jesu gegebi Olugbala ohun. Mohammodu mu baba re gba adura elese, leyin wakati meta, baba re fi aye sile. Ni apa kan, iku baba re je isele ibanuje, sugbon ni apa keji, o je isele ayo.
Kii se pe baba ati omo wa wa ni irepo kii baba Mohammodu to fi aye sile nikan,sugbon o fi aye sile ninu alaafia pelu imo wipe ninu aye ti o nbo, yio wa pelu Jesu titi ayeraye ati pelu ni ojo kan niwaju, yio wa pelu omo re ni orun.
Jesu Kristi ni: Jesu si wi fun, Emi ni ona, otito ati iye: ko si eniti o wa si odo Baba, bii ki se nipase mi. Johannu 14:6
A ro o ki o darapo mo idapo Kristieni ti o wa ni isale yii ki o tun bo le ni imo nipa ebun ofe iye ayeraye ninu Kristi Jesu.