Monday, 23 December 2024

Select your language

Tracts

Omo nikan lo le si ilekun

Omo nikan lo le si ilekun

Nigba ogun abele ni ile Amerika, soja kan wa ninu awon omo ogun Union, omodekunrin ti egbon re ati baba re ti ku s’ogun. O lo si Washington D. C. olu ilu Amerika lati rii Olori orile-ede, Ogbeni Lincoln lati beere fun iyonda kuro ninu ise ologun nitori kio baa lee ran iya re ati aburo re obinrin lowo lati se ise ogbin ni oko won.

Nigbati o de Washington leyin ti o ti gba aaye isinmi ranpe lenu ise ologun lati te pepe oro re, o losi ILE FUNFUN ( White House), o si ilekun, o beere lati ri olori orile-ede.

Amosa, won so fun wipe, “O le ri Olori orile-ede! Se iwo ko mo wipe ogun nlo lowo ni? Olori orile-ede ko raaye. Wa maa lo! Pada si oju ogun ki osi lo jaagun gege bi o se ye.”

O si jade sita pelu ogbe okan, o si joko si ori bensi kan ninu papa ti ko jina rara si White House nigbati omokunrin kekere kan si wa ba nibe.

Omo naa ni “Soja, oju re koro, se ko si?” Soja yii woo mode kunrin naa, o sib ere situ ifun ati edo re sita fun omo naa nipa oro re: bi baba ati egbon re ti se ku s’ogun ati bi ose je wipe ohun nikan ni okunrin tio ku ni idile won ati bi won se nilo re ni oko lati ran iya re ati aburo re obinrin lowo lati se ise oko.

Omodekunrin yii mu soja naa lowo daani osi mu gba ehinkunle White House. Won gba lekun eyin wole, won fi awon asona sile,bee naa ni won fi awom agbagba omoogun sile seyin ati awon to se pataki ninu ato ilu. Omodekunrin yii o ti wule kan lekun sugbon o si lekun o si wole. Ibe ni Olori orile-ede , Ogbeni Lincoln wa pelu Akowe Abele ti won se ayewo agbekale ilana ogun lori tabili. Ogbeni Lincoln gboju soke o si wipe, “Kini mole se fun o Todd?”

Todd si dahun wipe, “Baba mi, soja yii nilo lati ba yin soro.” Lesekese, soja naa ni aaye lati te pepe oro re niwaju ogbeni Lincoln, o si gba iyonda kuro ninu ise ologun nitori inira tio de ba.

Nje o fe iyonda kuro ninu laasigbo, ijiya ati inira ti ese ti fida aye loro? Nje o wu o lati di eni itusile kuro ninu igbekun Satani ati awon iranse ibi ati aje re?

Oo le lo si odo Omo Olorun. Yio mu owo re daani lo taara si iwaju Olorun Alagbara, Olori orile-ede agbaye, Eniti o da orun ati aye lati le ri aanu Oluwa gba.

Jesu ti san oyebiye fun igbala okan re kuro ninu iparun ayeraye eyi ti ese mu wa sori omo eniyan. O ta eje Re si’le nitori ese re lori igi agbelebu Kalfari.

Tewo gba ebun ofe idariji ese ati iye ayeraye.

Nibiti o wa yi, o le gbadura, ki o si jewo fun olorun pe gegebi gbogbo eniyan , pe elese ni o je ti o si nilo idariji lati odo olorun. Beere lowo Olorun fun idariji gbogbo ese re ni oruko Jesu Kristi, ki o si so fun Jesu Kristi ki o gba okan re laa, ki o si soo dii omo Olorun. Koju bee loo, ko nira rara.

Ranti wipe, nigbati o ba ti jewo ese re fun Olorun, pinu lati ko ese sile patapata.

Ti o ba nilo afikun tabi alaye, e kan si wa , inu wa yio si dun lati tubo se alaye si nipa ife Olorun ninu Kristi Jesu.

Popular Items //fa-pencil

Newsletter

Subscribe to our newsletter to get the latest updates from House of Karis

House of Karis Logo Footer

The House of Karis is a Christian publishing house focused on providing pure and truthful information that shall enable Christians live in righteousness and in the fear of God.

Email: bosun@houseofkaris.net

Search