Monday, 23 December 2024

Select your language

Tracts

Aiye Ki i se ayo tita

Aiye Ki i se ayo tita

Nkan tio o bada, iwo lo yaan

Ifilo Pataki ki o to yan ohunkohun

(Jowo ka itan yii awon ifilo to se koko wa ninu re fun awon ti owu lati se idibo pelu ogbon.)

Oloye Olowolagba Williams je oloro. O se aseyori to be ge ninu okowo re, ositun ni ile-ise janrere, opolopo oko ayokele to se iyebiye, ile nla ni awon agbegbe tio wuyi ati wipe o je eniyan ti won bo’wo fun gidigidi ni awujo gegebi onifaaji ati olojuaanu. Oni igbagbo pe eniyan daradara ni ohun je nitori kii saaba binu, o si maa n se iranlowo fun awon alaini ti o ba ri.

Ni ojo kan, leyin odun mokandinladorun lori eepe, oloye yii se alaisi leyin igbe aye olowo to ni aseyori. Leyin iku re, o han si wipe otito ni itan ti o ti gbo nipa pe awon onimo ojogbon se awari orun apaadi ni odun 1989. Orun apaadi gbona koja bee gee to je wipe o ju ti ajere lo.

Bayi, pelu gbogbo owo ati ipo ni aye, oloye yii yio lo ayeraye ninu ina to gbona gidigidi. Nigba aye re, oloye yii ko le fi omo ika re to kere ju (kurubete) si omi ti o hoo yaayaa lori ina.

Ninu irora ati ibanuje, o wu ki o ronupiwada kuro ninu ese re bii, iro pipa, agbere sise, afe aye, abbl, ofe re ara re sile lati gba igbala ti Jesu Kristi fi loo.

Fun ogoorun odun, egberun odun, odun millioni kan,odun billioni kan abbl,oloye Olowolagba yio wa ni orun apaadi. Ko dibo fun oludije tio kun oju osuwon nigba ayere. Oludije meji ni won fi iga gbaga fun aye re. Okan ni Jesu Kristi, omiran ni Sataani, esu.

Tio ba dibo fun Jesu, ijoba Re je eyi ti igboran ati ise ara eni se pataki. Yio beere fun ironupiwada (ji jewo ese ati ki ko ese sile) ati igboran lati owo re. Yio beere fun igbeaye iwa mimo, ire ara eni sile, igbeaye ni iwontuwonsi, ati iberu Olorun. Nigbati o ba ku, Jesu yio fun o ni iye ainipekun ni ijoba Olorun.

Tio ba dibo fun Sataani, yio fun o ni ominira lati see eleyi ti o ba wu o- bii oti mimu, ibalopo lai se igbeyawo, cigar mimu, ija jija, ilara, pipa awon ti o ba feran (ti o ba wu o lati se bee), ojukokoro owo, okiki nini ati wipe yio so di orisa ti o ba fe. Iwo koni ni idanilekun rara. Ko si eni ti yio so fun o pe nkan bayi ni ko see, nkan bayi ni kio maa see. Sugbon nigbati o ba ku, iwo yio dara po mo Esu ni orun apaadi titi lailai.

Ore mi, bawo ni iwo yio se dibo? Ogoorun odun si isinsiyi, ibo ni iwo yio wa?

Nje oti paro ri? Nje oti jale ri? Agbere nko? Nje oti fi oruko Oluwa se yeye tabi dapara bii? Nje o jebi tabi o jebi?

Dupe lowo Olorun pe osi wa laaye, oti di oku. Aaye si wa lati ronu piwada, beere idariji lowo Olorun ki o si gba irubo fun iwenumo ese ti Jesu Kristi fi loo o lori igi agbelebu fun ese re.

Wa ni airekoja. Re ara re sile. Beere aanu lowo Olorun ni oruko Jesu Kristi. Beere fun idariji ese re ati wipe ki okan re di gbigbala nipase Jesu Kristi.

Leyin eyi, wa ijo tio gbagbo ninu Bibeli ki o si sin Jesu Kristi.

Ranti, orun apaadi n duro, ko ni duro de o o. Nje omo wipe, olooye Olowolagba fe ran eniyan si awon ara ile re lati orun apaadi lati ki awon omo re nilo ati ebi re lati tun ona won se niwaju Oluwa ki won to ku. Amoo, ko si eni ti o le ran lo. Ko si ile ifiwe ranse ni orun apaadi.

DIBO PELU OGBON

O le gbadura nisinsiyi. Oluwa Alagbara, mo jewo pe mo tise, at wipe moti te ofin Re mole. Mo ronupiwada kuro ninu ese mi, mo si toro idariji ni oruko Jesu. Saanu fun mi, gba okan mi la kuro ninu iparun ayeraye nipase Jesu Kristi. So mi di eda tuntun ninu Kristi Jesu, funmi ni Emi Re. Modupe Baba orun, pe bi mo se gba ebun ofe igbala lati odo Jesu Kristi, mo di atunbi.

DIBO FUN OLUDIJE TI O TOO

 

Popular Items //fa-pencil

Newsletter

Subscribe to our newsletter to get the latest updates from House of Karis

House of Karis Logo Footer

The House of Karis is a Christian publishing house focused on providing pure and truthful information that shall enable Christians live in righteousness and in the fear of God.

Email: bosun@houseofkaris.net

Search