Friday, 29 March 2024

Select your language

Tracts

Igbala Nipase Ala (Itan Aliu)

Igbala Nipase  Ala (Itan Aliu)

Aliu ni agba ninu awon omo mesan sugbon ko ni itan ti o dara lati so pe ohun ko pa kan gbogi ninu ebi to tobi bi eleyi. Won maa n fi se yeye, won nipe oyato laarin awon ti o wa ninu ebi. Iya re ni ohun korira re ati wipe ohun nikan ni omo ti ko fi oju joo ohun. O gba wipe gbogbo ebi ni o ko ohun, o si maa n sun ekun ni opo igba nigbati o wa ni kekere.

Fun osu merin ninu odun kankan, Aliu maa n da eran aguntan. O bere eleyi lati omo odun mejo, o si se titi o fi pe omo odun mejidinlogun. Yio ko awon aguntan naa lo si ori oke, nigbati oti je wipe o maa n da nikan wa ni opo igba o wu lati le ba eniyan soro nitori be, o da “olorun kekere kan” sinu okan re. Olorun yii wa dabi ore Aliu. Aliu yio ba soro ti o gun gan ni bii, “Bawo ni ise re ti lewa to,” bi o ti nwo awon ododo, oorun, awon apata ati koriko. Yio bere lowo olorun kekere re yii ni awon ibeere bii, “Ibo ni adun ti o wa ninu eso “apple” ti wa?” nitori o gbagbo pe Olorun kan wa ti o da ohun gbogbo dara dara.

Nigbati o pe ogun odun, o beere si ni mu oti lile. Nigbati o pe omo odun marundinlogbon, o ti di oloti paraku. Nigba miran yio ti bere si ni mu oti lati aago mesan owuro. Nigbati o ba de ile, iyawo re yio beere lowo re ni opo igba boya oti mu oti. Eleyi ma mu inu bi ti o fi je wipe o bere si ni lu iyawo re bi bara ni ojojumo. Awon omo re maa n ri iwa ilokulo yii, eru si maa n ba won lati wa sile leyin ti won ba kuro ni ile-iwe nitori be,opo igba ni won yio lo si ile ore won kan lati duro sibe titi ile yio fi suu ti baba won yio ti sun.

Aliu fe siwo oti mimu, osi maa n dun pe ohun lo iyawo ohun nilokulo. O pinu lati lo si ile Saudi Arabia lati sise ikole nitori o gbo wipe won ko fi aye gba oti nibe. Ewe, ni asale akoko ti o de ile Saudi Arabia o se awari oti, o si mu.

Aliu kii se elesin-awon ebi re so wipe Musulumi ni awon sugbon ko ni imo nipa esin naa- o pinu lati lo ile Mecca, pelu erongba pe ohun yio di olominira kuro ninu oti mimu. O wipe- “Mo pinu ninu okan mi. Emi yio je alejo otito. Emi yio je Musulumi otito, emi yio sii fii oti mimu sile patapata.

Asale akoko ti o wa ni ile Mecca, Aliu la ala kan. Ninu ala yii, Jesu mu Aliu lowo dani, o si wi fun pe, “Emi ni mo ni o.” o si tun fii ika re kan iwaju ori Aliu O si wipe “Iwo nilo lati kuro nibiyi nisinsiyi.” Nigbati Aliu ji loju orun,ise ni o dabi wipe ohun fo ninu ofurufu nitori be ofi owo kan kapeti ti o bo ile lati se idaniloju pe ori ile ni o si wa.

O tesiwaju lati maa gbo ohun Jesu ti o n so wipe, “O nilo lati tele mi. Emi ni mo ni o.” Awon ore Aliu rip e aarin kan dan gbinrin niwaju ori re nibi ti Jesu ti fi owo kan, sugbon nigbati o lo wo ara re ninu digi,, ko le ri. (Ibi iwaju ori re yii dabi “sim” nkan ewa ti awon iyawo ile Turkey fi maa n se ara won loge.)

Aliu pinu lati tesiwaju ninu alejo re sise ni ile Mecca. Ewe, oko ayokele ti ko ti ju osu kan lo ko lati sise. Nse ni o gbo ohun Jesu ti o wipe, “O nilo lati kuro nihin.’ Gere ti o yi okan re pada lati fi ile Mecca sile,oko ayokele re sise. O pada lo sile re osi tun gbo ohun yi kan naa. Ni ote yii, Jesu wi fun pe ki o pada lo si orilede Turkey. Laarin ojo meta o wa nibi “aseye kabo paada sile” ni Turkey. Tunmo, o gbo ohun yii kan naa. Jesu wi fun peki o so fun gbogbo eniyan ti o wa nibi aseye yii pe ohun ti di Kristieni bayi. O se be sugbon awon eniyan ko gbagbo.

Leyin opolopo odun ti oti la ala yii ni Aliu bere si ni ni oye nkan ti o tumo si lati di Kristieni. Ise ni o ngbo ero asoromagbesi nigbati o gbo ohun ti o so wipe “Jesu ku, o jinde ni ojo keta, o si joko ni apa otun Baba.” O pe iyawo re o si so fun wipe ohun ti se awari ohun Jesu lori ero asoromagbesi. Nipase eto ori ero asoromagbesi yii, o gba awon ohun elo eko Bibeli ati Bibeli Majemu tuntun. Omo odun mejidinlogoji ni o je ni akoko yii, o si wipe ojo ti ohun gba Bibeli Majemu tuntun lati ile iwe ifiwe ranse ni lati je ojo ti inu ohun dun ju laye.” Nigbati o pari orisirisi awon eko, Aliu ati ebi re ko lo si ile Istanbul lati lo si ile-eko Bibeli. O tesiwaju lati maa fi igbagbo Kristieni re lo awon eniyan nita gbangba lai si ti oju. Oti ko ni ijoba lori re mo, o feran iyawo re eniti o ti se aida si teleri. Nitoto, o ti di eda tuntun ninu Kristi.”

A gba o ni iyanju ki o darapo mo idapo Kristieni ti o wa ni isale yii ki o le tubo nimo si nipa ebun ofe iye ayeraye ninu Kristi Jesu.





Popular Items //fa-pencil

Newsletter

Subscribe to our newsletter to get the latest updates from House of Karis

House of Karis Logo Footer

The House of Karis is a Christian publishing house focused on providing pure and truthful information that shall enable Christians live in righteousness and in the fear of God.

Email: bosun@houseofkaris.net

Search