Saturday, 10 May 2014 00:00

Owo ti o san idiyele

Written by 
(0 votes)

Overview

Omokunrin kekere kan ti awon obi re ti se alaisi n gbe l’odo iya baba re. L’oru ojo kan ile won gba ina. Iya baba re nibiti o ti n tiraka lati gba omo yii laa nitori o ti sun si ori oke petesi ile won, eefin ati ina ni o pa iya agbalagba yii.

Awon eero suru bo ile ti o njona. Igbe omo naa fun iranlowo han ketekete pelu ariwo ina naa. Kosi enikeni ti o mo nkan ti won le se, nitori pe iwaju ile naa ti gba ina patapata.

Lojiji ajeji kan sare lati inu ero o si yipo losi ehinkunle nibiti oju re ti ri opa irin ti o gun de ferese yara oke. O di awati fun iseju kan, igbati o f’oju sita, omodekunrin naa wa ni owo re. Pelu atewo ati ikini lati odo ogoro eniyan, o sokale laara opo irin ti o ti gbona pelu omo naa ti o so moo ni orun.

Leyin ose pupo ijiroro ita gbangba wa’ye larin gbogan ilu lati se iwadi odo eniti omodekunrin naa yio maa gbe.

Onikaluku ti o fe omo naa ni akata re ni o ni aaye lati so’ro ni soki. Eni akoko wipe, “Moni oko nla. Gbogbo eniyan lo nilo ati sere ni ita gbangba.” Eni keji so gbogbo anfaani ti ohun le pese. “Oluko ni mi. moni yara ikawe nla. Yio gba eko to dara.”

Awon elomiran soro.

Nipari, eniti o ni owo ju ni agbegbe naa soro, “Olowo ni mi. Emi yio fun ni ohun gbogbo ti ati daruko ni asele yii: oko, eko ati pupo sii, pelu owo ati irin ajo. Emi yio fe ki omo naa wa si inu ile mi.”

Alaga ijoko wa beere “Nje elomiran fesoro bii?”

Lati ijoko eyin ni ajeji kan ti dide eniti o yoo wole. Bi o se rin si iwaju, irora to rinle naa han ni oju re. Nigbati o de iwaju gbogan ijiroro, o duro niwaju omo naa gangan. Ajeji yii sii mu owo re meji jade diedie lati inu apo re. Iho isemi jade laarin awon ero. Omo naa, eniti o nwo ile lati igba ti ijiroro naa ti bere,gboju soke.

Owo okunrin naa ti joo koja bee.

Lojiji, omo naa kigbe sita pe ohun mo okunrin naa. Eniti o gba emi re la. Owo re ti jonaa nibiti oti gun opa irin gbigbona ati nigbati o sokale. Omo naa baa fo mo ajeji yii lorun osi diimu sinsin.

Agbe dide o si lo. Oluko naa lo. Leyin naa, olowo. Gbogbo eniyan lo patapata, won si fi omokunrin yii ati “olugbala” eniti o jere re lai wi ohunkohun sile. Awon owo ti o jo na guruguru fohun ju oro tiba so lo.

Nje mole bio o ni ibere ti ko le yii? Opolopo esin ni o wa lorile ede agbaye, abi? Ewo ninu awon oludasile awon esin wonyi ni o jiya ati ti ose irubo pelu emi re ki o ba le ni iye ayeraye?

Kosi, ayafi Jesu Kristi. Owo ati ese Kristi Jesu si ni ami iso ti won fi kan mo igi agbelebu nitori ese re.

Gbadura nisinsiyi, so fun Jesu ki o dari ese re ji o, ki osi gba okan re la.

Leyin eyi, o le kan si wa fun ekunrere alaaye.

 

BLOG COMMENTS POWERED BY DISQUS

Calendar

« November 2020 »
Mon Tue Wed Thu Fri Sat Sun
            1
2 3 4 5 6 7 8
9 10 11 12 13 14 15
16 17 18 19 20 21 22
23 24 25 26 27 28 29
30