Saturday, 10 May 2014 00:00

Igbala Nipase Ala (Itan Khosrowu)

Written by 
(3 votes)

Overview

Lati kekere ni Khosrowu ti maa n beere awo ibeere orisirisi bii “itumo aye.” Gbogbo nkan ni yio beere ibeere nipa re. kini idi abajo ti awon ododo fi ni awo? Kini o wa leyin awon irawo? Ibo ni anlo nigbati a ba ku? Awon eniyan wo lo wa ninu ero mohunmaworan?

Nibo ni won lo nigbati ero mohunmaworan yii ba wa ni pipa? Nigbati kosi eni ti o le dahun awon ibeere re ki osi telelorun, ise ni o ri sinu ironu ti o koro gidigidi.

Ni ojo kan nigbati o wa ni odomokunrin, o rin koja ile ijoosin Kristieni ti Assyriani kan o si pinu lati wo inu re, o si lero pe ohun yio ri idahun si awon ibeere ohun nibe. Awon agbalagba obinrin die ni o wa nibe ati alufaa agbalagba kan ti o gbe apoti iwe kan fun. Awon iwe naa ni o wa ni ede Farsi (ede ile Iran) lara awon iwe naa ni eda Bibeli majemu tuntun wa, ti Khosrowu ka lati pali de pali. Sugbon iriri kika awon iwe naa nikan ko to lati fun ni idahun si awon ibeere. O fon awon iwe naa si ile yara ninu iporuru okan re. Ni akoko yii aworan okunrin kan wa ba loju iran. Arakunrin yii naa owo re si Khosrowu o si so fun: “Mu owo mi dani ohun gbogbo yio si yi pada titi lai.” Khosrowu mu okunrin naa lowo daani, isegiri bi ina gba ara re koja. O kunle, o si bere si ni sunkun, ti o pariwo gaan ni ti awon obi re si sare lo si yara re. Iyalenu nla gbaa ni fun won lati ri omo won ti o n sunkun fun igba akoko leyin ogoro odun.

Iran ti Khosrowu ri yii kii se agbekale ohun ti o ro ni okan. O pada si odo Alu fa Assyriani ti o ko awon iwe naa fun o si se alaaye iriri re. Bi odun ti n gori odun, Khosrowu n dagba gegebi omoleyin Kristi, leyinoreyin ohun naa wa di alufaa. Sugbon ijiya deba awon omo leyin Kristi ni orile-ede Iran ti osi mu ki o sa asala fun emi re lo si orile-ede Turkey pelu iyawo re ati omo meji. Ijiya ati isoro naa wa ni ile Turkey sugbon Khosrowu ati ebi re jere awon eniyan nipase suru ati ife. Khosrowu fi opolopo ile ijoosin lole ni orilede Turkey ki ohun ati awon ebi re to sa kuro ni Turkey. Ni ote yi won se atipo ni orilede Austria. Won wo oko ojuofurufu lati Turkey lo si Bosnia won si fi ese rin gba ona ori oke lale lati ibe. Nigbati won da odo kan koja; omo Khosrowu, Josefu, si ese gbe lori agbeloro afara osi subu si inu omi ti o tutu bi yinyin, o si fa baba re si isale naa pelu. Odo yi n ho yaya o si jin, Khosrowu gbiyanju lati se awari omo re ninu omi dudu, sugbon ko ri omo naa. Ewe, iyawo re naa fo sinu omi lati se iranlowo, sugbon die lo ku ki omi gbe lo.

Lojiji, Khosrowu, dede ri wipe bi igbati eniyan kan baa gbe Josefu si owo re. O si tun ri wipe o dabi pe eniyan kan (ti ko le fi oju ri ) fun ni iranlowo lati dide duro ninu omi ti o si tun gbe Josefu si ebute odo ona. Gbogbo won ni won ni akoyo ati ebi pelu, won si ni amumora ati aforiti lati la awon ewu miran koja, won si de Austria layo.

Khosrowu se agbeyewo owo ti ko le fi ojuri ti o ko ohun ati ebi re yoo ni ale ojo naa si owo ti o ri ti o si kan lara ninu iran nipa Jesu ti o ri. O so itan alaigbagbo kan ti o bi ni ibeee nipa bi oti se mo wipe iran ti ori yii kii se ero okan re. Khosrowu da alaigbagbo yii lohun wipe nje oti wule wo aso bii. Kayefi se okunrin naa pelu ibeere naa, sugbon afiwe naa han taaraa. Iran ti Khosrowu rii se ododo gegebi o se da okunrin naa loju pe ohun wo aso ati pelu awon ohun miran.

A ro o ki o darapo mo idapo isin Kristieni ni isale yii ki osi ko eko si nipa ebun ofe iye ayeraye ninu Kristi Jesu.

BLOG COMMENTS POWERED BY DISQUS

Calendar

« July 2020 »
Mon Tue Wed Thu Fri Sat Sun
    1 2 3 4 5
6 7 8 9 10 11 12
13 14 15 16 17 18 19
20 21 22 23 24 25 26
27 28 29 30 31