Saturday, 10 May 2014 00:00

Igbala Nipase Ala (Itan Dini)

Written by 
(0 votes)

Overview

Gegebi agba omo ninu ebi re, Dini, eni odun mejila sunmo baba re gaan ni ti ofi je wipe, ibanuje de baa nigbati baba re ku lojiji. Ibanuje re yipada si ibinu nigbati o gbo wipe baba re se asemase pelu aburo iya re tio si ti loyun. Odi mimo si Dini pe iya re naa wa ninu oyun.

Gegebi opo t’ohun tiraka, iya Dini pinu lati ko awon omo re meta tio kekere ju si ilea won omo alaini baba. O ta awon dukia won ki ebi re le ri owo lati jeun. Leyin odun merin, ara ile kan so fun Dini pe iya re ti fe fe elomiran. Oro yii dun Dini gaan ni, ko siye idi ti iya re ko fi so fun. O ro wipe kosi eniti ohun le gbojule lati fi se awokose nigbati baba re ti fun ni ijakule, iya re ti se bakanaa.

Dini di ore pelu awon onijagidijagan ni ile-iwe, osi la akoko iselodi koja. Ko ni losi iyara-ikeko, ko ni wo aso ile-iwe, o si tun maa n ja. Nigbati pupo ninu awon ore re dojuko isoro ti o le, Dini bere si beere ibeere: “Kini ohun ti o mohun wa? Ofin esin ko mu inumidun. Sugbon igbeaye ti oni itoni ofin esin kii se ohun ti mohun wa rara.”

Osu awe de, Dini si se dede pelu awon isesi awe ati adura. Ni oru ojo kan, ninu osu awe, o pinu lati gbadura tahajud. Adura tahajudi kiise okan lara adura maarun ojojumo. Eleyi ni won maa n gba ni dede aago mejila oru ati wipe, won yio rawo ebe si olorun fun ami. Dini fi aago ijini si wakati ti o fe ji, o si ji lati gbadura. O wipe, “Mo ni igbagbo tio rin le wipe ohunkohun ti mo ba beere fun ni asele ojo naa, Oluwa yio gbo, yio si fun mi ni idahun re.” Leyin adura ti oti se agberu gbeso re, o ke si Olorun o si wipe, “Olorun, nkan ti daru mo mi loju. Ona ti mo le to wa si odo re lati gba ifowosi re ko ye mi.” O tesiwaju, “Olorun, ti o ba wu o lati je kin gbe aye ninu ife re, ni asale yii, fi ona ti o tona han mi, Ti iwo ko baa fii han mi, Olorun je kin gbe igbe aye mi bi oti wu mi. Mi o fe pa ofin esin mo mo. Bi mo ba si ku, mase ran mi lo si orun apaadi. Emi ko mo ohun ti o je otito! Ko ni je idajo ti o tona lati ranmi lo si orun apaadi, Olorun. Iwo ko fi ona otito han mi. Ohun ti mo fe, Olorun, ni ki o fi ona otito han mi ni asale oni. Emi yio gbe igbe aye mi bi iwo ba se lana re.”

Ina kan dede tan ti o si mole yoo, osi ri aworan kan ti o duro niwaju re. Okunrin naa wo aso funfun sugbon ko ri oju re taara. Ko mo bi o se mo pe aworan yii ti Isa ni. O wi fun pe, “ Tele mi,” idaru de ba o si ro lokan re wi pe, “Oluwa, Musulumi ni emi je. Bawo ni emi yio se tele o?” O beere opolopo ibeere miran bi o ti n ro bi ohun yio se tele Olorun awon Kristieni. O gbo ohun miran to wi fun, “Ko se se fun o lati tele e. Gbagbe adura re! Gbagbe erongba re lati gbe igbe aye ti o dara!”

Nigbati o wo okunrin alaso funfun , o ni itura ati ibaleokan. Jesu tesiwaju lati so fun, “Tele mi,” bi O ti se naa owo Re sii. Dini jijakadi lori ipinu re sugbon o so wipe “ Olorun ti o ba je wipe ona otito ni yii, o dara. Emi yio tele O.” Ni oju ese ti o so eleyi, ise ni o dabi igba ti yinyin ba da si aya re. Ni akoko yii kan naa, alaafia de ba ti ko ri iru re rii. O wi pe, “Nkan araoto wa si okan mi.”

Leyin ti Dini di Kristieni, awon ara ile re gbogun tii. Omo odun metadinlogun ni ti won fi ipa le jade nile. Ile-iwe aladagbe ni ohun lo, o si n sise pepepe leyin ile-iwe lati ri owo fi toju ara re. O si tun le ipa irepo laarin ebi re. Bi oti fun awon asa ati ise ile re ni owo, ko ye ninu akitiyan re si Kristi. Idanwo ti o gaju fun nipe ki o dariji baba re ti oti ku, ki osi gba aburo re okunrin ti aburo iya re bi fun baba re lai se igbeyawo. Nigbati iya omokunrin yii ko le toju re mo, Dini gba aburo re mora gege bi t’ara re.

O tesiwaju lati ma gbe igbeaya t’oni apeere eniti “O le se ohun gbogbo nipase Kristi ti o fun ni okun.”

A gba o ni iyanju lati darapo mo idapo Kristieni ti o wa ni isale yii ki ole ni imo si nipa ebun ofe iye ayeraye ninu Kristi Jesu.BLOG COMMENTS POWERED BY DISQUS

Calendar

« November 2020 »
Mon Tue Wed Thu Fri Sat Sun
            1
2 3 4 5 6 7 8
9 10 11 12 13 14 15
16 17 18 19 20 21 22
23 24 25 26 27 28 29
30