Saturday, 10 May 2014 00:00

Igbal A Nipase Ala(Itan Khalilu)

Written by 
(0 votes)

Overview

Khalilu bere si ni ko akosori lati inu Kurani lati igba kekere osi feran oro Olorun. Bi o se ndagba si, o bere si ni ka iwe lori esin Islam ati itumo si Kurani. Bi o se se iyato laarin eni ti oje Musulumi ati eni ti kii se Musulumi gegebi eko ti o ri ko ninu Kuran.

O tile ri awon obi re gegebi alaigbagbo. Awon nkan ti ko se kasi bii kii obinrin maafi aso ibori tabi ijaabu boju re so iru obinrin bee di alaigbagbo ni ilana Musulumi, gege bi o ti ri ka ninu Kurani. Bakan naa ni o ri okunrin ti ko baa da irun agbon re si bii alaigbagbo. O ri awon Kristieni gegebi ota re ti o buru ju lo. O si beere sii kolu won ati ile ijoosin won.

Egbe Musulumi kan ti o fara won jin lati dite gba ijoba ni ile Eygipiti ti won si fe yan ijoba Musulumi nikan sori alefa gba Khalilu si aarin won lati ma bawon sise gegebi adari ibile. Egbe re yii ni won wa nidi jiji gbe gbajugbaja onkowe Musulumi kan ti o gbiyanju lati bu enu ate lu egbe yii.

Leyinoreyin, owo awon agbofinro te Khalilu; odun meji ni o lo ni ogba ewon, ti won si fi iya je daadaa, leyin ti won fi sile, o kuro ni Eygipiti lo si ilu Yemeni pelu awon odaju Musulumi kan.

Leyin ti o ka iroyin kan ninu iwe iroyin Cairo nipa awon Kristieni ti owo awon agbofinro te nitori won polongo ihinrere, Khalilu ati awon omo egbe re gbimo pe asiko ti to lati se nkan fun esin Islamu.

Pelu iwonba kereje ti won je, won pinu pe, ogun naa yio je ti opolo sise iwadi ati kiko iwe lati fihan gbangba pe Mohammodu ni woli Olorun tooto, ati wipe Bibeli awon Krietieni ati Jeu iwe idibaje ni.

Khalilu ni oludari egbe yii yan lati se iwaadi ati lati ko iwe naa. Khalilu ko jale lakoko, sugbon o gba lati se ise naa nigbati o ya; leyi ti ose apejuwe re gegebi ise ti ko wuyi ju lo ti ohun se ri.

Nigbati opari Bibeli kika ati afiwe sise nkan tio ti ka pelu awon ohunkan jokan iwe esin Islamu, iyalenu ni oje fun Khalilu lati ri wipe Bibeli kii se wipe ko kojun osunwon tabi pe idibaje baa. Sugbon iyalenu nio j e fun lati ri awon eko Bibeli lori idariji ati ife aisetan gegebi bi o se farahan ninu aye ati oro Jesu.

Kayefi nla lo se lati ka bii Jesu se ki awon omo leyin re nilo nipa ijiya ti eleyi si n sele ni egberun odun meji leyin ti Kristi baa won omo leyin re soro yii. O si ribe gegebi Jesu se soo. Kika Bibeli re ranlowo lati je ki oni oye idi abajo ti awon Kristieni ilu Eygipiti kii se gbesan ti awon Musulumi ba se ibi tabi aida si won, ati bi o se rorun fun won lati dariji ati lati gbagbe. Bi o ti korira kika Bibeli to, o bere si ni feran iwaasu ati oro inu re.

Lai fi eyi se, ise wa fun lati se, osi tesiwaju pelu ipinu ti o daju, o yan lati fihan wipe Jesu kii se Olorun ati wipe won ko kan mo agbelegbu. Sise ayewo Kurani fun idi eyi, ose akopo awon iwa ati riri Olorun. Gegebi Kurani se so, Olorun ni Eleda, Oluwosan, Olupese, Enikan soso ti o le ji oku dide, Oniseyanu, Oludajo tiki se oju saaju abbl. Si iyalenu re, Khalilu ri wipe awon iwa wonyi ni Kurani so nipa Jesu (Yisa) tio si fidi re mule ni odo Khalilu pe Jesu ati Olorun mbe, okan ni won je.

Ni ojo kan, oga re se abewo si odo Khalilu ninu ile re, osi ri abajade iwadi ti Khalilu ti ko sinu iwe (bii Jesu se je OLorun, bii Kurani kii se oro Olorun abbl). Ko le gbagbo pe ohun ti ohun ka niyi. O so fun Khalilu pe ohun yio pa ti awon abajade iwadi re ba di hihan si awon Musulumi miran ati wipe, Khalilu funra re ti di alaigbagbo si ohun (oga).

Ewe, Khalilu ko le yi okan re kuro ninu idaniloju ti o ti ni wipe esin Kristieni ni ona ti o tona. O fe ni imo si, o darapo mo ile ijoosin kan. Eniti o ti je ajijagbara Musulumi teleri, kosi enikeni ti oni igbekele tabi igbagbo ninu re. Ewe, ohun kan ninu re sofun wipe ki o maa se gbekele eniyan. Ni ojo kan bi oti nse gbiyanju lati lo ero ibanisoro ni ile itaja kan, won ji eru re lo. Ninu eru yii ni awon iwe ti oti ko wa ti ole mu wahala ba, be sini kaadi idanimo re wa ninu eru yii. O saare lo sile, pelu iporuru okan. O we, o sig be eni jade lati kirun, sugbon ko le bere lati orokun re, beni ko si le la enu re lati gbadura lati inu Kurani. O joko sile, o si wipe, Olorun iwo mo pe monife re ati wipe mo mo wipe o fe kin wa ni ona otito. Oluwa , mi o le ko mo. Gbogbo ohun ti mo tise, mo se lati te iwo Olorun lorun ni. Jowo, fa mi kuro ninu okunkun yii.

Ni asale ojo naa, Khalilu sun bi ko ti se sun ri. Ninu ala, ori okunrin kan ti o wa ba, osi wi fun pe ohun ni eniti Khalilu ti nwa. Khalilu ko mo okunrin naa. Okunrin naa so fun pe ki o lo wo inu Iwe (Bibeli) Khalilu so wipe Iwe naa ati gbogbo iwe ti ohun ti ko ti sonu, eyi ti okunrin naa fesi wipe, “Iwe naa kii sonu. Dide, sii ibi ikohunkan si re, iwo yio rii ni be. Awon iwe re yio di didapada leyin ipari ose.”

Khalilu taji lati oju orun, osi si ibi ikohunkansi re. Bibeli tarare gangan wa ninu ibe. O mo wipe Jesu ni ohun ri, o saare losi yara iya re, oji iya re loju orun, o bebe fun idariji fun gbogbo aida ti oti se si ebi re latigbayi wa. Wiwa ona atunse ko tan si odo awon ebi re nikan.

Bi ile se ti mo, Khalilu gbona ode lo, o bere sii kii awon ore ati ajeji bakanaa. O se awari awon olusowo ti o je Kristieni ti oti fo ile itaja won tabi ti oti se aito si won, o beere fun idariji lati owo won naa pelu.

Bi osu se n gori osu, khalilu n dagba si ninu esin re titun, igboya de fun ati igbekele lati odo awon Kristieni ti o wa ni agbegbe re, o si wa ile ijoosin kan darapo mo. Won se iribomi fun, kosi ko ewu ti o wa fun emi re tori pe o gba Jesu ni Olugbala re, nitori pe ko si idiyele kan ti o poju lati san fun Eniti o jowo ohun gbogbo sile nitori tire.BLOG COMMENTS POWERED BY DISQUS

Calendar

« November 2020 »
Mon Tue Wed Thu Fri Sat Sun
            1
2 3 4 5 6 7 8
9 10 11 12 13 14 15
16 17 18 19 20 21 22
23 24 25 26 27 28 29
30